1 Timothy 6:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo pa á láṣẹ fún àwọn ọlọ́rọ̀ ayé yìí, pé kí wọ́n má ṣe ní ọkàn gíga. Bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n má ṣe gbára lé ọrọ̀ tí kò lágbẹkẹ̀lé, ṣugbọn kí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun tí ó ń fún wa ní gbogbo ọrọ̀ fún ìgbádùn wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kìlọ fun awọn ti o lọrọ̀ li aiye isisiyi, ki nwọn máṣe gberaga, bẹni ki nwọn máṣe gbẹkẹle ọrọ̀ aidaniloju, bikoṣe le Ọlọrun alãye, ti nfi ohun gbogbo fun wa lọpọlọpọ lati lo;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìṣinṣinyìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò se lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ láti lò;