2 Chronicles 1:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun dá Solomoni lóhùn pé, “Nítorí pé irú èrò yìí ló wà lọ́kàn rẹ, ati pé o kò sì tọrọ nǹkan ìní, tabi ọrọ̀, ọlá, tabi ẹ̀mí àwọn ọ̀tá rẹ, o kò tilẹ̀ tọrọ ẹ̀mí gígùn, ṣugbọn ọgbọ́n ati ìmọ̀ ni o tọrọ, láti máa ṣe àkóso àwọn eniyan mi tí mo fi ọ́ jọba lé lórí,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun si wi fun Solomoni pe, Nitoriti eyi wà li aiya rẹ, ti iwọ kò si bère ọrọ̀, ọlà, tabi ọlá, tabi ẹmi awọn ọta rẹ, bẹ̃ni o kò tilẹ bère ẹmi gigun, ṣugbọn o bère ọgbọ́n fun ara rẹ, ki o le ma ṣe idajọ enia mi, lori ẹniti mo fi ọ jọba:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run wí fún Solómónì pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìfẹ́ ọkàn rẹ nìyí, tí ìwọ kò sì béèrè, fún ọrọ̀, ọlá tàbí ọ̀wọ̀, tàbí fún ikú àwọn ọ̀ta rẹ, àti nígbà tí ìwọ kò ti béèrè fún ẹ̀mí gígùn, ṣùgbọ́n tí ìwọ béèrè fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti ṣàkóso àwọn ènìyàn mi tí èmi fi ọ́ jẹ ọba lé lórí,