2 Chronicles 1:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn oníṣòwò a máa ra kẹ̀kẹ́ ogun kan ni ẹgbẹta (600) ìwọ̀n ṣekeli fadaka wá fún Solomoni láti Ijipti, wọn a sì máa ra ẹṣin kan ní aadọjọ (150) ìwọ̀n ṣekeli fadaka. Àwọn náà ni wọ́n sì ń bá a tà wọ́n fún àwọn ọba ilẹ̀ Hiti ati ti ilẹ̀ Siria.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gòke, nwọn si mu kẹkẹ́ kan lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu ẹṣin jade fun gbogbo awọn ọba ara Hitti, ati fun awọn ọba Siria nipa wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ra kẹ̀kẹ́ kan láti Éjíbítì. Fún ọgọ́rùn ún mẹ́fà Sékélì (6,000) fàdákà àti ẹṣin kan fún ọgọ́rin-méjì-ó-dínláàdọ́ta. Wọ́n ko wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọba mìíràn ti Hítì àti ti àwọn ará Árámíà.