2 Chronicles 1:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Solomoni ati àwọn tí wọ́n péjọ lọ sí ibi gíga tí ó wà ní Gibeoni, nítorí pé àgọ́ ìpàdé Ọlọrun tí Mose, iranṣẹ OLUWA, pa ninu aginjù wà níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Solomoni ati gbogbo awọn ijọ enia pẹlu rẹ̀, lọ si ibi giga ti o wà ni Gibeoni; nitori nibẹ ni agọ ajọ enia Ọlọrun gbe wà, ti Mose, iranṣẹ Oluwa ti pa ni aginju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú Sólómónì, àti gbogbo àpéjọ lọ sí ibi gíga ní Gíbíónì, nítorí àgọ́ Ọlọ́run fún pípàdé wà níbẹ̀, tí Móse ìránṣẹ́ OLÚWA ti kọ́ ni ihà.