2 Chronicles 10:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
ó sọ̀rọ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́ fún un, ó ní, “Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn èmi óo tún fi kún àjàgà náà. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi máa ta yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si da wọn li ohùn gẹgẹ bi imọran awọn ipẹrẹ, wipe, Baba mi mu àjaga nyin ki o wuwo, ṣugbọn emi o fi kún u; baba mi ti fi paṣan nà nyin, ṣugbọn emi o fi akẽke nà nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́mọdé, ó sì wí pé, “Baba mi mú kí àjàgà yín wúwo; Èmi yóò sì mú kí ó wúwo jùlọ. Baba mi nà yín pẹ̀lú pàṣán; Èmi yóò sì nà yín pẹ̀lú àkéekèé.”