2 Chronicles 10:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Rehoboamu kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dáhùn pé, “Kí ló kàn wá pẹlu ilé Dafidi? Kí ló pa wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese? Ẹ pada sinu àgọ́ yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli Dafidi, fọwọ́ mú ilé rẹ.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lọ sí ilé wọn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kọ̀ lati fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba lohùn, wipe, Ipin kili a ni ninu Dafidi? awa kò si ni ini kan ninu ọmọ Jesse: Israeli, olukuluku sinu agọ rẹ̀: nisisiyi Dafidi, mã bojuto ile rẹ. Bẹ̃ni gbogbo Israeli lọ sinu agọ wọn,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti wọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé: “Ìpín kí ní a ní nínú Dáfídì, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jésè? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ìwọ Ísírẹ́lì! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dáfídì!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sí ilé wọn.