2 Chronicles 10:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọba rán Hadoramu tí ó jẹ́ olórí àwọn akóniṣiṣẹ́ sí àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. Rehoboamu ọba bá yára bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá àsálà lọ sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Rehoboamu ọba ran Hadoramu ti iṣe olori iṣẹ-irú; awọn ọmọ Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Ṣugbọn Rehoboamu ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀ lati salọ si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Réhóbóámù rán Ádónírámù jáde, ẹni tí ó wà ní ìkáwọ́ iṣẹ́ onírúuru, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ọ́ ní òkúta pa. Ọba Réhóbóámù bí ó tí wù kí ó rí, gbìyànjú láti dé inú kẹ̀kẹ́ rẹ̀ ó sì sálọ sí Jérúsálẹ́mù.