2 Chronicles 10:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n gbà á ní ìmọ̀ràn pé, “Bí o bá ṣe dáradára sí àwọn eniyan wọnyi, tí o bá ṣe ohun tí ó tẹ́ wọn lọ́rùn, tí o sì sọ̀rọ̀ dáradára fún wọn, wọn yóo máa sìn ọ́ títí lae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si ba a sọ̀rọ pe, bi iwọ ba ṣe ire fun enia yi, ti iwọ ba ṣe ohun ti o wù wọn, ti o ba si sọ̀rọ rere fun wọn, nwọn o ma ṣe iranṣẹ rẹ nigbagbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì dáhùn, “Tí ìwọ yóò bá ṣe rere sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kí o sì ṣe ire fún wọn kí o sì fún wọn ní ìdáhùn rere, wọn yóò sì máa jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ nígbà gbogbo.”