2 Chronicles 11:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Rehoboamu dé Jerusalẹmu, ó kó ọ̀kẹ́ mẹsan-an (180,000) àwọn akọni ọmọ ogun jọ láti inú ẹ̀yà Juda ati Bẹnjamini, láti bá àwọn ọmọ Israẹli jagun, kí ó lè fi ipá gba ìjọba rẹ̀ pada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI Rehoboamu si de Jerusalemu o kó ile Juda ati Benjamini jọ, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba Israeli jà, ki o le mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Réhóbóámù dé Jérúsálẹ́mù, ó kó ilé Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́sàn án ènìyàn tí a yàn, tí wọ́n jẹ́ ológun, láti bá Ísírẹ́lì jà kí ó lè mú ìjọba naà padà bọ̀ sọ́dọ̀ Réhóbóámù.