2 Chronicles 11:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Lefi fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ ati ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n kó wá sí Juda, ati Jerusalẹmu; nítorí pé Jeroboamu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lé wọn jáde, wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alufaa Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti awọn ọmọ Lefi fi ìgberiko wọn silẹ, ati ini wọn, nwọn si lọ si Juda ati Jerusalemu: nitori Jeroboamu ati awọn ọmọ rẹ̀ ti le wọn kuro lati ma ṣiṣẹ alufa fun Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ará Léfì fi ìgbéríko sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Júdà àti Jérúsálẹ́mù nítorí Jéróbóamù àti àwọn ọmọ rẹ̀, ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà OLÚWA.