2 Chronicles 11:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ sin Ọlọrun Israẹli tọkàntọkàn láti inú olukuluku ẹ̀yà Israẹli, tẹ̀lé àwọn alufaa wá sí Jerusalẹmu láti ṣe ìrúbọ sí OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin wọn iru awọn ti o fi ọkàn wọn si ati wá Oluwa Ọlọrun Israeli lati inu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli wá, si wá si Jerusalemu, lati ṣe irubọ si Oluwa Ọlọrun awọn baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn tó wá láti gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n fi ọkàn wọn fún wíwá OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, tẹ̀lé àwọn ará Léfì lọ sí Jérúsálẹ́mù láti lọ rúbọ sí OLÚWA Ọlọ́run bàbá a wọn.