2 Chronicles 11:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Maaka, ọmọ Absalomu ni Rehoboamu fẹ́ràn jùlọ ninu àwọn iyawo rẹ̀. Àwọn mejidinlogun ni ó gbé ní iyawo, o sì ní ọgọta obinrin mìíràn. Ó bí ọmọkunrin mejidinlọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Rehoboamu si fẹran Maaka ọmọbinrin Absalomu, jù gbogbo awọn aya rẹ̀ ati àle rẹ̀ lọ: (nitoriti o ni aya mejidilogun, ati ọgọta àle: o si bi ọmọkunrin mejidilọgbọn ati ọgọta ọmọbinrin).
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Réhóbóámù fẹ́ràn Mákà ọmọbìnrin Ábúsálómù ju èyí kejì nínú àwọn ìyàwó rẹ̀ àti àwọn àlè rẹ̀ lọ. Ní gbogbo rẹ̀, ó ní ìyàwó méjìdínlógún àti ọgọ́ta àlè ọmọkùnrin méjìdínlọ́gbọ̀n àti ọgọ́ta ọmọbìnrin.