2 Chronicles 11:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó dọ́gbọ́n fi àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe olórí káàkiri, ó pín wọn káàkiri jákèjádò ilẹ̀ Juda ati Bẹnjamini ní àwọn ìlú alágbára. Ó fún wọn ní ohun tí wọ́n ṣe aláìní. Ó sì fẹ́ iyawo fún gbogbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si huwà ọlọgbọ́n, o si tú ninu gbogbo awọn ọmọ rẹ̀ ka si gbogbo ilẹ Juda ati Benjamini, si olukuluku ilu olodi: o si fun wọn li onjẹ li ọ̀pọlọpọ. O si fẹran ọ̀pọlọpọ obinrin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó hùwà ọlọ́gbọ́n, nípa fí fọ́nká díẹ̀ nínú àwọn ọmọ rẹ̀ jákè jádò ká àwọn agbégbé Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti sí gbogbo àwọn ìlú ńlá aláàbò. Ó fún wọn ní ọ̀pọ̀ ohun tí wọ́n fẹ́, ó sì gba ọ̀pọ̀ ìyàwó fún wọn.