2 Chronicles 11:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ bá àwọn arakunrin yín jà. Kí olukuluku yín pada sí ilé rẹ̀ nítorí èmi ni mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ó ṣẹlẹ̀.’ ” Wọ́n gbọ́ràn sí OLUWA lẹ́nu, wọ́n pada, wọn kò sì lọ bá Jeroboamu jagun mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi, ẹnyin kò gbọdọ gòke lọ, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ba awọn arakunrin nyin jà: ki olukuluku pada si ile rẹ̀: nitori ọ̀ran yi lati ọdọ mi wá ni. Nwọn si gbà ọ̀rọ Oluwa gbọ́, nwọn si yipada kuro lati lọ iba Jeroboamu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Èyí ní ohun tí OLÚWA wí. Ẹ má ṣe gòkè lọ lati lọ jà pẹ̀lú arákùnrin yín, ẹ lọ sílé, gbogbo yín, nítorí ti ìṣe mi nìyí.’ ” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì padà sẹ́yìn láti yan lọ dojúkọ Jéróbóámù.