2 Chronicles 12:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Rehoboamu fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní Jerusalẹmu, agbára rẹ̀ sì pọ̀ sí i. Ọmọ ọdún mọkanlelogoji ni nígbà tí ó jọba. Ó jọba fún ọdún mẹtadinlogun ní Jerusalẹmu, ìlú tí OLUWA yàn láàrin àwọn ẹ̀yà yòókù, pé kí wọ́n ti máa sin òun. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Naama, ará Amoni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Rehoboamu ọba mu ara rẹ̀ le ni Jerusalemu, o si jọba: nitori Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹtadinlogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Réhóbóámù fi ara rẹ̀ lélẹ̀ gidigidi ní Jérúsálẹ́mù, ó sì tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógójì nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba fún ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ní Jérúsálẹ́mù, ìlú ńlá tí OLÚWA ti yàn jáde kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní èyí tí ó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ sí.
Recommended Reading