2 Chronicles 12:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ohun tí Rehoboamu ṣe, láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ni a kọ sinu ìwé ìtàn wolii Ṣemaaya, ati sinu ìwé Ido aríran. Nígbà gbogbo ni ogun máa ń wà láàrin Rehoboamu ati Jeroboamu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ iṣe Rehoboamu, ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kò ha kọ wọn sinu iwe Ṣemaiah, woli, ati ti Iddo, ariran, nipa iwe itan idile? Ọtẹ si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu nigbagbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún tí iṣẹ́ ìjọba Réhóbóámù láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìrantí ti Ṣémáíà wòlíì àti ti Idò, aríran tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá? Ìtẹ̀ṣíwájú ogun jíjà sì wà láàárin Réhóbóámù àti Jéróbóámù.