2 Chronicles 12:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ati ọ̀kẹ́ mẹta (60,000) ẹlẹ́ṣin, ati ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e láti Ijipti. Àwọn ará Libia, àwọn ará Sukiimu, ati àwọn ará Etiopia wà ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlu ẹgbẹfa kẹkẹ́, ati ọkẹ́ mẹta ẹlẹṣin: awọn enia ti o ba a ti Egipti wá kò niye; awọn ara Libia, awọn ara Sukki, ati awọn ara Etiopia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú ẹgbẹ̀fà kẹ̀kẹ́ (12, 000) àti ọkẹ́ mẹ́ta àwọn ọkùnrin ẹlẹ́ṣin àti àìníye ọ̀wọ́ ogun ti Líbíyánì, Ṣúkísè àti Kúṣì, tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ láti Éjíbítì.