2 Chronicles 12:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, wolii Ṣemaaya lọ bá Rehoboamu ati gbogbo àwọn olóyè Juda, tí wọ́n ti péjọ sí Jerusalẹmu lórí ọ̀rọ̀ Ṣiṣaki ọba Ijipti. Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA ní ẹ ti kọ òun sílẹ̀, nítorí náà ni òun ṣe fi yín lé Ṣiṣaki lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Ṣemaiah, woli, tọ̀ Rehoboamu wá, ati awọn ijoye Juda, ti o kojọ pọ̀ si Jerusalemu nitori Ṣiṣaki, o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, enyin ti kọ̀ mi silẹ, nitorina li emi si ṣe fi nyin silẹ si ọwọ Ṣiṣaki.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà naà, wòlíì Ṣémáíà wá sí ọ̀dọ̀ Réhóbóámù àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí Júdà tí wọ́n ti péjọ ní Jérúsálẹ́mù nítorí ìbẹ̀rù Ṣíṣáki, ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí OLÚWA wí: ìwọ ti pa mí tì; nítorí náà èmi náà ti pa yín tì sí ọ̀dọ̀ Ṣíṣákì.”