2 Chronicles 12:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti ronupiwada, ó sọ fún wolii Ṣemaaya pé, níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, òun kò ní pa wọ́n run mọ́, ṣugbọn òun óo gbà wọ́n sílẹ̀ díẹ̀. Òun kò ní fi agbára lo Ṣiṣaki láti rọ̀jò ibinu òun sórí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Oluwa ri pe nwọn rẹ̀ ara wọn silẹ, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Ṣemaiah wá, wipe, Nwọn ti rẹ̀ ara wọn silẹ; nitorina emi kì o run wọn, ṣugbọn emi o fun wọn ni igbala diẹ: a kì yio dà ibinu mi sori Jerusalemu nipa ọwọ Ṣiṣaki.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí OLÚWA ríi pé, wọ́n ti rẹ̀ ara wọn sílẹ̀ ọ̀rọ̀ OLÚWA yí tọ Ṣémáíà lọ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀, Èmi kì yóò pa wọ́n ṣùgbọ́n, yóò fún wọn ní ìtúsílẹ̀ tó bá yá. Ìbínú mi kì yóò dà sórí Jérúsálẹ́mù ní pasẹ̀ Ṣíṣákì.