2 Chronicles 12:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣiṣaki bá gbógun ti Jerusalẹmu, ó kó gbogbo ìṣúra ilé OLUWA lọ, ati ti ààfin ọba patapata, ati apata wúrà tí Solomoni ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, goke wá si Jerusalemu, o si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; o kó gbogbo rẹ̀: o kó awọn asà wura lọ pẹlu ti Solomoni ti ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ṣíṣákì ọba Éjíbítì dojúkọ Jérúsálẹ́mù, ó gbé àwọn ìṣúra ilé OLÚWA, àti àwọn ìsúra ààfin ọba. Ó gbé gbogbo rẹ̀, pẹ̀lú àwọn àpáta wúrà tí Sólómónì dá.