2 Chronicles 13:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn ní tiwa, OLUWA Ọlọrun ni à ń sìn; a kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ọmọ Aaroni ni àwọn alufaa wa, àwọn ọmọ Lefi sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi o ṣe ti wa ni, Oluwa li Ọlọrun wa, awa kò si kọ̀ ọ silẹ ati awọn alufa, ti nṣe iranṣẹ fun Oluwa, ani awọn ọmọ Aaroni ati awọn ọmọ Lefi ninu iṣẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ti àwa, OLÚWA ni Ọlọ́run wa, àwa kò sì ti ì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àwọn àlùfaà tí ó ń sin OLÚWA jẹ́ àwọn ọmọ Árónì àwọn ará Léfì sì n ràn wọ́n lọ́wọ́.