2 Chronicles 13:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àràárọ̀ ati ní alaalẹ́ ni wọ́n ń rú ẹbọ sísun, tí wọ́n sì ń sun turari. Wọ́n ń fi àkàrà ìfihàn sórí tabili wúrà. Ní alaalẹ́, wọ́n ń tan fìtílà wúrà lórí ọ̀pá fìtílà rẹ̀; nítorí àwa ń ṣe ohun tí Ọlọrun wa pa láṣẹ fún wa, ṣugbọn ẹ̀yin ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si nsun ọrẹ-ẹbọ sisun ati turari didùn li orowurọ ati li alalẹ si Oluwa: àkara ifihan pẹlu ni nwọn si ntò lori tabili mimọ́; ati ọpa fitila wura pẹlu fitila wọn, lati ma jó lalalẹ; nitori ti awa npa aṣẹ Oluwa Ọlọrun wa mọ́; ṣugbọn ẹnyin kọ̀ ọ silẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àràárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbé ọrẹ sísun àti tùràrí olóòórùn dídùn síwájú OLÚWA. Wọ́n gbé àkàrà jáde sórí tábìlì àsè mímọ́, wọ́n sì tan iná sí àwọn fìtílà lórí ìdúró ọ̀pá fìtílà wúrà ní gbogbo ìrọ̀lẹ́. A ń pa àṣẹ OLÚWA Ọlọ́run wa mọ́. Ṣùgbọ́n ìwọ ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀.