2 Chronicles 13:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun wà pẹlu wa, òun fúnrarẹ̀ ni aṣaaju wa. Àwọn alufaa rẹ̀ wà níhìn-ín láti fun fèrè láti pè wá kí á gbógun tì yín. Ẹ̀yin eniyan Israẹli, ẹ má ṣe bá OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín jà, nítorí ẹ kò ní borí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si kiyesi i, Ọlọrun tikararẹ̀ si wà pẹlu wa li Olori wa, ati awọn alufa rẹ̀ pẹlu ipè didún ijaiya lati dún si nyin, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ máṣe ba Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin jà; nitori ẹ kì yio ṣe rere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa; òun ni olórí wa. Àwọn àlùfáà rẹ̀ pẹ̀lú fèrè wọn yóò dún dídùn ogun sí i yín. Ẹyin ọkùnrin Ísírẹ́lì, Ẹ má ṣe dojú ìjà kọ OLÚWA Ọlọ́run baba a yín nítorí ẹ̀yin kì yóò yege.”