2 Chronicles 13:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Abija kó ogún ọ̀kẹ́ (400,000) akọni ọmọ ogun jọ láti bá Jeroboamu jagun. Jeroboamu náà kó ogoji ọ̀kẹ́ (800,000) akọni ọmọ ogun jọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Abijah si fi awọn alagbara akọni ologun dì ogun na, ani ogún ọkẹ́ enia ti a yàn, Jeroboamu pẹlu si fi ogoji ọkẹ enia ti a yàn, awọn alagbara akọni enia tẹ́ ogun si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ábíjà lọ sí ojú ogun pẹ̀lu àwọn ọmọ ogun ogún ọ̀kẹ́ (40,000) ọkùnrin alágbára, Jéróbóámù sì fa ìlà ogun sí i pẹ̀lu ogójì ọ̀kẹ́ (8,000) ọ̀wọ́ ogun tí ó lágbára.