2 Chronicles 13:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sì lọ kó àwọn jàǹdùkú ati àwọn aláìníláárí eniyan kan jọ, wọ́n pe Rehoboamu ọmọ Solomoni níjà. Rehoboamu jẹ́ ọmọde nígbà náà, kò sì ní ìrírí tó láti dojú ìjà kọ wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia lasan si ko ara wọn jọ si ọdọ rẹ̀, awọn ọmọ ẹni buburu, nwọn si mu ara wọn le si Rehoboamu, ọmọ Solomoni, nigbati Rehoboamu wà li ọdọmọde ti inu rẹ̀ si rọ̀, ti kò si le kò wọn loju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn lásán aláìwúlò péjọ yí i ká, wọ́n sì kẹ̀yìn sí Réhóbóámù ọmọ Sólomónì ní ìgbà tí ó sì kéré tí kò lè pinnu fún ra rẹ̀, tí kò lágbára tó láti takò wọ́n.