2 Chronicles 13:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ ti lé àwọn alufaa OLUWA kúrò lọ́dọ̀ yín: àwọn ọmọ Aaroni, ati àwọn ọmọ Lefi. Ẹ yan alufaa mìíràn dípò wọn bí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣe. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá ti mú akọ mààlúù tabi aguntan meje wá, ẹ̀ ń yà á sí mímọ́ fún iṣẹ́ alufaa àwọn oriṣa tí kì í ṣe Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin kò ha ti lé awọn alufa Oluwa jade, awọn ọmọ Aaroni, ati awọn ọmọ Lefi, ẹnyin si ti ṣe awọn alufa fun ara nyin, gẹgẹ bi iṣe awọn orilẹ-ède ilẹ miran? bẹ̃ni ẹnikẹni ti o ba wá, ti ọwọ rẹ kún pẹlu ọdọ-akọ-malu ati àgbo meje, on na le ma ṣe alufa awọn ti kì iṣe ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ṣé ìwọ kò lé àwọn àlùfáà Ọlọ́run jáde, àwọn ọmọ Árónì àti àwọn ará Léfì. Tí ó sì se àwọn àlùfáà ti ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ mìíràn ti ṣe? Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá láti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù àti àgbò méjì lè jẹ́ àlùfáà èyí tí kì í ṣe àwọn Ọlọ́run.