2 Chronicles 14:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Asa ké pe OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kò sí olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ nítorí pé o lè ran àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lágbára lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn tí wọ́n lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, OLUWA Ọlọrun wa, nítorí pé ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ní orúkọ rẹ ni a jáde láti wá bá ogun ńlá yìí jà. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun wa, má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣẹgun rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Asa si ke pe Oluwa Ọlọrun rẹ̀, o si wipe, Oluwa! lọdọ rẹ bakanna ni fun ọ lati ràn alagbara enia lọwọ, tabi ẹniti kò li agbara: ràn wa lọwọ, Oluwa Ọlọrun wa; nitori ti awa gbẹkẹ le ọ, li orukọ rẹ li awa ntọ ọ̀pọlọpọ yi lọ, Oluwa, iwọ li Ọlọrun wa; máṣe jẹ ki enia ki o bori rẹ,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, Ásà ké pe OLÚWA Ọlọ́run baba a rẹ̀, ó sì wí pé “OLÚWA kò sí ẹnìkan bí ì rẹ láti rán aláìlágbára lọ́wọ́láti dójú kọ ẹni ńlá. Ràn wá lọ́wọ́, OLÚWA Ọlọ́run wa, nítorí tí àwa gbẹ́kẹ̀ lé ọ àti ní orúkọ rẹ ni àwa fi wá láti dojúkọ àwọn ọ̀pọ̀ ọmọ-ogun yìí. OLÚWA, ìwọ ni Ọlọ́run wa; má se jẹ́ kí ènìyàn kó ṣẹ́gun rẹ.”