2 Chronicles 14:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Asa ati àwọn ogun rẹ̀ lé wọn títí dé Gerari. Ọpọlọpọ àwọn ará Etiopia sì kú tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè gbá ara wọn jọ mọ́; wọn sì parun patapata níwájú OLUWA ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Juda sì kó ọpọlọpọ ìkógun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Asa ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ lepa wọn de Gerari: a si bi awọn ara Etiopia ṣubu ti ẹnikan kò tun wà li ãye; nitori ti a ṣẹ́ wọn niwaju Oluwa ati niwaju ogun rẹ̀; nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ikogun lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ásà àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ sá tẹ̀lé wọn ní jìnnà réré sí Gérárì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, àwọn ará Kúṣì ṣubú, wọn kò sì le sán padà mọ́. A fún wọn pa níwájú OLÚWA àti ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọkùnrin Júdà kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógún.