2 Chronicles 14:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n wó gbogbo àgọ́ àwọn tí ń sin mààlúù, wọ́n sì kó ọpọlọpọ aguntan ati ràkúnmí wọn pada sí Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si kọlù awọn agbo-ẹran-ọsin, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ agutan ati ibakasiẹ lọ, nwọn si pada wá si Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n kọ lu àwọn ibùdó àwọn darandaran, wọ́n sì gbé àwọn ọ̀wọ́-ẹran àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ àti àwọn ìbákasẹ. Nígbà náà wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù.