2 Chronicles 14:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá sọ fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ Juda pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́ àwọn ìlú wọnyi, kí á mọ odi yí wọn ká pẹlu ilé ìṣọ́, kí á kan ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè wọn, kí á sì fi àwọn ọ̀pá ìdábùú sí wọn. Ìkáwọ́ wa ni gbogbo ilẹ̀ náà wà, nítorí pé à ń ṣe ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa. A ti wá ojurere rẹ̀, ó sì fún wa ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà.” Wọ́n kọ́ àwọn ìlú náà, wọ́n sì ń ní ìtẹ̀síwájú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si sọ fun Juda pe, Ẹ jẹ ki a kọ́ ilu wọnni, ki a si mọdi yi wọn ka, ati ile-iṣọ, ilẹkun ati ọpa-idabu, nigbati ilẹ na si wà niwaju wa, nitori ti awa ti wá Oluwa Ọlọrun wa, awa ti wá a, on si ti fun wa ni isimi yikakiri. Bẹ̃ni nwọn kọ́ wọn, nwọn si ṣe rere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ jẹ́ kí a kọ́ àwọn ìlú wọ̀nyí” Ó wí fún Júdà, “Kí ẹ sì mọ odi yí wọn ká pẹ̀lú àwọn ile ìṣọ́ gíga, àwọn ẹnu ọ̀nà òde, àti àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀. Ilé náà ti wà, nítorí a ti bèrè lọ́wọ́ OLÚWA Ọlọ́run wa; a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì ti fún wa ní ìsinmi ní gbogbo ọ̀nà.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kọ́ ọ, wọn sì ṣe rere.