2 Chronicles 14:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Asa ọba ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ọmọ ogun ní ilẹ̀ Juda, tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀ ati ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) láti Bẹnjamini tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọrun. Gbogbo wọn ni a ti kọ́ ní ogun jíjà tí wọ́n sì jẹ́ akọni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Asa si ni ogun ti ngbé asà ati ọ̀kọ, ọkẹ mẹdogun lati inu Juda wá, ati lati inu Benjamini wá, ọkẹ mẹrinla ti ngbé apata ati ti nfa ọrun: gbogbo wọnyi si ni akọni ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ásà ní àwọn ọmọ ogun ti ó jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (300,000) àwọn ọkùnrin láti Júdà. Pẹ̀lú àwọn ohun èlò àwọn àpáta ńlá àti ọ̀kọ̀ àti ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá (280,000) láti Béńjamẹ́nì wọ́n dira pẹ̀lú àwọn apata kékèké àti àwọn ọrun. Gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́ ògbójú jagunjagun ọkùnrin.