2 Chronicles 14:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sera, ará Etiopia, gbógun tì wọ́n pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun (1,000,000) ọmọ ogun ati ọọdunrun (300) kẹ̀kẹ́ ogun. Wọ́n sì jagun títí dé Mareṣa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Sera, ara Etiopia, si jade si wọn, pẹlu ãdọta ọkẹ enia, ati ọ̃dunrun kẹkẹ́; nwọn wá si Mareṣa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣérà ará Kúṣì yàn láti dojú kọ wọ́n, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọmọ ogun pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta kẹ̀kẹ́, wọ́n sì wá láti jìnnà réré bí Máréṣà.