2 Chronicles 15:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n mú ẹẹdẹgbẹrin (700) mààlúù ati ẹẹdẹgbaarin (7,000) aguntan ninu ìkógun tí wọ́n kó, wọ́n fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun baba wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi ninu ikógun ti nwọn kó wá, rubọ si Oluwa li ọjọ na, ẹ̃dẹgbãrin akọ-malu ati ẹ̃dẹgbãrin agutan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò yìí, wọ́n rúbọ sí OLÚWA ọgọ́rùnún méje akọ màlúù àti ẹgbẹ̀rún ḿéje (7,000) àgùntàn àti àwọn ewúrẹ́ láti ibi ìkogun tí wọ́n ti kó padà.