2 Chronicles 15:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Asa ọba, yọ Maaka ìyá rẹ̀ àgbà pàápàá kúrò ní ipò ìyá ọba, nítorí pé ó gbẹ́ ère ìríra kan fún oriṣa Aṣera. Asa wó ère náà lulẹ̀, ó gé e wẹ́lẹwẹ̀lẹ, ó sì dáná sun ún ní odò Kidironi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu Maaka, iya Asa, li ọba mu u kuro lati má ṣe ayaba, nitoriti o yá ere fun oriṣa rẹ̀: Asa si ké ere rẹ̀ lulẹ, o si tẹ̀ ẹ mọlẹ, o si sun u nibi odò Kidroni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba Ásà rọ ìyá ńlá rẹ̀ Mákà lóyè láti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyá ọba nítorí tí ó ti ṣe òpó Áṣérà tí ń lé ni sá. Ásà gé òpó náà lulẹ̀, wòó, ó sì jóo ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì.