2 Chronicles 15:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó lọ pàdé Asa, ó wí fún un pé, “Gbọ́ mi, ìwọ Asa, ati gbogbo ẹ̀yin ọmọ Juda ati ti Bẹnjamini, OLUWA wà pẹlu yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin náà bá wà pẹlu rẹ̀. Bí ẹ bá wá a, ẹ óo rí i. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, òun náà yóo kọ̀ yín sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si jade lọ ipade Asa, o si wi fun u pe, Ẹ gbọ́ temi, Asa, ati gbogbo Juda ati Benjamini! Oluwa pẹlu nyin, nitori ti ẹnyin ti wà pẹlu rẹ̀; bi ẹnyin ba si ṣafẹri rẹ̀, ẹnyin o ri i; ṣugbọn bi ẹnyin ba kọ̀ ọ, on o si kọ̀ nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó jáde lọ bá Ásà, ó sì wí fún un pé, “Tẹ́tí si mi Ásà, àti gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì. OLÚWA wà pẹ̀lú rẹ, nígbà tí ìwọ bá wà pẹ̀lú rẹ̀. Ti ìwọ bá wá a, ìwọ yóò rí i ní ẹ̀bá rẹ ṣùgbọ́n tí ìwọ bá kọ̀ ọ́ silẹ̀, òun yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀.