2 Chronicles 15:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Asa gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Asaraya ọmọ Odedi sọ, ó mọ́kàn le. Ó kó gbogbo ère kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Juda ati gbogbo ilẹ̀ Bẹnjamini ati ní gbogbo àwọn ìlú tí wọ́n gbà ní agbègbè olókè Efuraimu. Ó tún pẹpẹ OLUWA tí ó wà níwájú yàrá àbáwọlé ilé OLUWA ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Asa gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, ati asọtẹlẹ Odedi woli, o mu ara le, o si mu awọn ohun irira kuro lati inu gbo-gbo ilẹ Juda ati Benjamini, ati lati inu ilu ti o ti gbà lati oke Efraimu, o si tun pẹpẹ Oluwa ṣe, ti o wà niwaju iloro Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Ásà gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí àti àsọtẹ́lẹ̀ Ásáríyà ọmọ Ódédì wòlíì, ó mú àyà rẹ̀ le. Ó gbé àwọn òrìsà ìkóríra kúrò ní gbogbo ilẹ̀ Júdà àti Bẹ́ńjámínì àti kúrò nínú àwọn ìlú tí ó ti fi agbára mú ní ori òkè Éfúráímù. Ó tún pẹpẹ OLÚWA ṣe tí ó wà ní iwájú Pórífíkò ti ilé OLÚWA