2 Chronicles 15:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó kó gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Bẹnjamini jọ, ati àwọn tí wọ́n wá láti Efuraimu, Manase ati Simeoni, tí wọ́n jẹ́ àlejò láàrin wọn. Nítorí pé ọpọlọpọ eniyan láti ilẹ̀ Israẹli ni wọ́n ti sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọ́n rí i pé OLUWA Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si kó gbogbo Juda ati Benjamini jọ, ati awọn alejo ti o pẹlu wọn lati inu Efraimu ati Manasse, ati lati inu Simeoni wá: nitori ti nwọn ya li ọ̀pọlọpọ sọdọ rẹ̀ lati inu Israeli wá, nigbati nwọn ri pe, Oluwa Ọlọrun rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà naà, ó pe gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì jọ àti àwọn ènìyàn láti Éfúráímù, Mánásè àti Síméónì tí ó ti ṣe àtìpó ní àárin wọn. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti Ísírẹ́lì nigbà tí wọ́n rí i wí pé OLÚWA Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀