2 Chronicles 16:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kẹrindinlogoji ìjọba Asa, ní ilẹ̀ Juda, Baaṣa ọba Israẹli gbógun ti Juda, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mọ odi Rama láti dí ojú ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Juda, kí ẹnikẹ́ni má baà lè lọ sí ọ̀dọ̀ Asa, ọba Juda, kí àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ má sì lè jáde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LI ọdun kẹrindilogoji ijọba Asa, Baaṣa, ọba Israeli, gòke wá si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má ba jẹ ki ẹnikan ki o jade, tabi ki o wọle tọ̀ Asa, ọba Juda lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Ásà, Básà ọba Ísírẹ́lì gòkè wá sí Júdà ó sì kọlu Rámà, láti ma bàá jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Ásà ọba Júdà lọ.