2 Chronicles 16:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀rọ̀ yìí mú kí inú bí Asa sí wolii Hanani, ó sì kan ààbà mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ ninu túbú, nítorí inú bí i sí i fún ohun tí ó sọ. Asa ọba fi ìyà jẹ àwọn kan ninu àwọn ará ìlú ní àkókò náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Asa si binu si ariran na, o si fi i sinu tubu; nitoriti o binu si i niti eyi na. Asa si ni ninu awọn enia na lara li akokò na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ásà sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Ásà sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.