2 Chronicles 16:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọdún kọkandinlogoji ìjọba Asa, àrùn burúkú kan mú un lẹ́sẹ̀, àrùn náà pọ̀ pupọ. Sibẹsibẹ, ninu àìsàn náà kàkà kí ó ké pe OLUWA fún ìwòsàn, ọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn ni ó lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li ọdun kọkandilogoji ijọba rẹ̀, Asa ṣe aisan li ẹsẹ rẹ̀, titi àrun rẹ̀ fi pọ̀ gidigidi: sibẹ ninu aisan rẹ̀ on kò wá Oluwa, bikòṣe awọn oniṣegun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kọkàndínlógójì (39) ìjọba rẹ̀, Ásà sì ṣe àìsàn pẹ̀lú àrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Lákókò àrùn rẹ̀ ó múná, kó dà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ OLÚWA, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan.