2 Chronicles 16:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n sin ín sinu ibojì òkúta tí ó gbẹ́ fúnrarẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n tẹ́ ẹ sórí àkéte, tí ó kún fún oniruuru turari tí àwọn tí wọ́n ń ṣe turari ṣe. Wọ́n sì dá iná ńlá kan láti ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si sìn i sinu isa-okú, ti o gbẹ́ fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, nwọn si tẹ́ ẹ lori àkete ti a fi õrun-didùn kùn, ati oniruru turari ti a fi ọgbọ́n awọn alapolu pèse: nwọn si ṣe ijona nlanla fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì sin ín sínú ìsà òkú tí ó ti gbé jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dáfídì. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dìdùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n àwọn alápòlù pèsè, wọ́n sì ṣe ìjóná ńlá nínú ọlá ńlá rẹ̀.