2 Chronicles 16:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Asa bá kó àwọn eniyan jọ jákèjádò Juda, wọ́n lọ kó òkúta ati pákó tí Baaṣa fi ń kọ́ Rama, wọ́n lọ fi kọ́ Geba ati Misipa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Asa ọba kó gbogbo Juda jọ; nwọn si kó okuta ati igi Rama lọ, eyiti Baaṣa nfi kọ́le; o si fi kọ́ Geba ati Mispa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ní ọba Ásà kó gbogbo àwọn ènìyàn Júdà jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rámà lọ èyí ti Básà ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Gébà àti Mísípà.