2 Chronicles 16:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà ni Hanani aríran, wá sọ́dọ̀ Asa, ọba Juda, ó wí fún un pé, “Nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, dípò kí o gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun rẹ, àwọn ogun Siria ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li àkoko na Hanani, ariran, wá sọdọ Asa, ọba Juda, o si wi fun u pe, Nitoriti iwọ gbẹkẹle ọba Siria, iwọ kò si gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun rẹ, nitorina ni ogun ọba Siria ṣe bọ́ lọwọ rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà wòlíì Hánánì wá sí ọ̀dọ̀ Ásà ọba Júdà, ó sì wí fún un pé, “nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀ lé ọba Árámù, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀ lé OLÚWA Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Árámù ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ.
Recommended Reading