2 Chronicles 16:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ojú OLUWA ń lọ síwá sẹ́yìn ní gbogbo ayé láti fi agbára rẹ̀ hàn fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí i. Ìwà òmùgọ̀ ni èyí tí o hù yìí; nítorí pé láti ìsinsìnyìí lọ nígbàkúùgbà ni o óo máa jagun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti oju Oluwa nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ̀. Ninu eyi ni iwọ hùwa aṣiwere: nitorina lati isisiyi lọ ogun yio ma ba ọ jà.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ojú OLÚWA yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”