2 Chronicles 17:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn kan ninu àwọn ará Filistia mú ẹ̀bùn ati fadaka wá fún Jehoṣafati gẹ́gẹ́ bíi ìṣákọ́lẹ̀. Àwọn ará Arabia náà sì mú ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) àgbò, ati ẹgbaarin ó dín ọọdunrun (7,700) òbúkọ wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu awọn ara Filistia mu ọrẹ fun Jehoṣafati wá, ati fadakà owo ọba: awọn ara Arabia si mu ọwọ́-ẹran fun u wá, ẹgbãrin àgbo o di ọ̃dunrun, ati ẹgbãrin obukọ di ọ̃dunrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lára àwọn ará Fílístínì, mú ẹ̀bùn fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó ọba wá fún Jéhóṣáfátì, àwọn ará Árábíà sì mú ọ̀wọ́ ẹran wá fún-un, ẹgbàrin ó dín ọ̀dúnrún àgbò àti ẹgbarìndín ní ọ̀ọ́dúnrún òbúkọ.

Recommended Reading