2 Chronicles 17:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà OLUWA fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, gbogbo àwọn ọmọ Juda sì ń san owó orí fún un. Nítorí náà ó di ọlọ́rọ̀ ati ọlọ́lá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni Oluwa fi idi ijọba na mulẹ li ọwọ rẹ̀; gbogbo Juda si ta Jehoṣafati li ọrẹ, on si li ọrọ̀ ati ọlá li ọ̀pọlọpọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì fi ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lábẹ́ àkóso rẹ̀, gbogbo Júdà sì mú ẹ̀bùn wá fún Jehóṣáfátì, Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ní ọrọ̀ àti ọlá lọ́pọ̀lọpọ̀.