2 Chronicles 17:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n bá wọn lọ ni: Ṣemaaya, Netanaya, ati Sebadaya; Asaheli, Ṣemiramotu, ati Jehonatani; Adonija, Tobija ati Tobadonija. Àwọn alufaa tí wọ́n tẹ̀lé wọn ni Eliṣama ati Jehoramu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati pẹlu wọn, o rán awọn ọmọ Lefi, ani Ṣemaiah, ati Netaniah, ati Sebadiah, ati Asaheli, ati Ṣemiramotu, ati Jehonatani, ati Adonijah, ati Tobijah, ati Tob-Adonijah, awọn ọmọ Lefi; ati pẹlu wọn Eliṣama, ati Jehoramu, awọn alufa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì ní díẹ̀ lára àwọn ọmọ Léfì, àní Ṣémáyà, Netaníà, Sebadíà, Ásáélì, Ṣémírámótì, Jéónátanì, Àdóníjà, Tóbíyà àti Tobi-Àdóníjà àti àwọn àlùfáà Élíṣámà àti Jéhórámù.