2 Chronicles 18:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn wolii yòókù ń sọ bákan náà, wọ́n ń wí pé, “Lọ gbógun ti Ramoti Gileadi, o óo ṣẹgun. OLUWA yóo fi wọ́n lé ọba lọ́wọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe, Gòke lọ si Ramoti-Gileadi, iwọ o ṣe rere; Oluwa yio si fi i le ọba lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn wòlíì tí ó kù ni wọn ń sọtẹ̀lẹ́ ní àkókò kan náà, “Wọ́n sì wí pé, dojúkọ Rámótì Gílíádì ìwọ yóò sì ṣẹ́gun,” wọ́n wí pé, “nítorí OLÚWA yóò fi lé ọba lọ́wọ́.”