2 Chronicles 18:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Iranṣẹ tí ó lọ pe Mikaya sọ fún un pé, “Àsọtẹ́lẹ̀ kan náà ni gbogbo àwọn wolii ń sọ, pé ọba yóo ṣẹgun, ìwọ náà sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah si wi fun u pe, Kiye si i, awọn woli fi ẹnu kan sọ rere fun ọba: Njẹ emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọkan ninu ti wọn, ki o si sọ rere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìránsẹ́ tí ó ti lọ pe Míkáyà sì wí fún un pé, “Ẹ wò ó, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin kan àti òmíràn wòlíì fi ẹnu kan sọ rere fún ọba. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kí ó níí ṣe pẹ̀lú ti wa, kí o sì sọ rere.”