2 Chronicles 18:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó dé iwájú Ahabu, Ahabu bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Mikaya, ṣé kí á lọ gbógun ti Ramoti Gileadi tabi kí á má ṣe lọ?” Mikaya dáhùn pé, “Ẹ lọ gbógun tì í, OLUWA yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, ẹ óo sì ṣẹgun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si tọ̀ ọba wá, ọba sọ fun u pe, Mikaiah, ki awa ki o lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? O si wipe, Ẹ lọ, ẹnyin o si ṣe rere, a o si fi wọn le nyin lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ó dé, ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, “Míkáyà, se kí àwa ki ó lọ sí ogun ti Rámótì Gílíádì, tàbí kí àwa kí ó fàsẹ́yìn?” “Ẹ dojú kọ wọ́n kí ẹ sì ṣẹ́gun.” Ó dahùn, “nítorí a ó fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.”